Wednesday 6 September 2017

IWE EPE DANU
Efun die, Osun die, Edu Die, ewe awerepepe ojo, ao koko gun Efun loto, Osun Loto, edu loto, ao waa gun Ewe awerepepe pelu ose dudu, ao fi owo mun Ogun ina si ao gun po, ao waa da osun si ao po po daadaa, ao tun Efun si ao po po daadaa, ao waa da edu si ao po mo ar won daadaa, ao ko sinu ike kan ao gbodo gbe si inu ile o, eyinkule ni ao ma gbe si, ti aba fe lo, ao bu die ni ibe lo si odo, ao ko eyin si ibi ti odo ti nsan bo ao koju si ibiti omi naa nsan lo, ao maa we.

Ao fi iyere Osun te ifa Ejiogbe ao waa pe ohun si bayi,

Ohun re
Para Pahun 3x
Oju Orun o lenini
Adifa fun Orunmila nigbati o nti ikole orun bo wa si ikole aiye, Won ni ile aiye ti o nlo yi, awon Elepe nbe nibe, Awon alasasi nbe nibe, Awon Alasan nbe nibe awon Alfa, woli Babalawo ika nbe nibe etc oni toba se bi ise temi Lagbaja omo Lagbaaja ni oni
Efun ni nba aiye osun je
Osun ni nba aiye efun je
Ati efun ati osun Edu ni ba ye won je
Gbogbo epe won lori emi lagbaja Omo Lagbaja ati efun ati osun edu ni nba aiye won je, ki gbogbo epe ori mi asasi ori mi, asan, epe idile baba, epe idile iya etc Ati efun ati osun edu ni nba aiye won je.  Toripe enikan ki se ina koma le joni, Awerepepe ooo, Epe idile baba epe idile iya, Epe ota lori emi lagbaja omo lagbaja ki o waa pe gbogbo e danu lori mi lati oni lo, odo ki san kobu oju wo eyin... Adua, ao waa daa mo ose eyiti abu ti afe lo wa yen, ao lo we.


IKILO
ti aba fe lo we aso ti awolo ao gbodo wo pada wale mo, ao si gbodo wo eyin titi ao fi dele, Ojo meta lao we ose yi lera lera, Odaju

No comments:

Post a Comment