Friday, 1 September 2017


ORO NIPA IRAWO EDA
A nfi asiko yii ki gbogbo eyin Ololufe Egbe Ewe Nje (BEN) Aku Odun Oni, emi gbogbo waa yio se pupo re laye amin. Oro nipa Irawo Eda, Opo Obi loti da irin ajo Omo re ru lori Ise Kiko Iwe Kika, Iran Merin ni Olohun Oba daa si ile aiye yii, Ohun lo fa ti Iwa gbogbo waa ko le fi dogba, Alfa Olorin kan sope (song) ema fi omo we omo ki eberu Olohun 2x Eniba fi omo we omo yio lu omo re pa, ema fi omo we omo ki eberu Olohun.

Ohun ti mo fe fayo ninu oro yii ni wipe, Olohun ko da eda bakana, Won le biwa ni osu kan naa sugbon ki o maa je ojo kan naa tabi Igba kanaa, Olukuluku Eda pata lo mun Irawo, Ise, Iwa ti yio maa wu laye wa lati Orun, Irawo merin ti a nso oro re yii ni
1. Irawo Omi
2. Irawo ina
3. Irawo Ategun
4. Irawo Iyepe

Eri awon Irawo mererin yii, Iwa won ko le dogba laye, Ohun ni akiyesi ti mo fe ki Opo ninu wa koni, igbamiran waa ti baba ba bi omo sile, Bi iru omo yii baa wu iwa buruku kan, Baba re asope Omo yii ko fi iwa jomi, Kole fi iwa jo e raaraa toripe Iran irawo ti iwo je ole je omo tie ko jebe.

Igba miran waa ti o ye ki a ni akiyesi gidi lori irawo wiwo yii, Papa julo lori awon omo waa, Oye ki a tete gbe igbese lori iru Iran irawo ti won je toripe, Opo enia lo ro wipe, ti Ogun kan baa ti nja won, won a lero wipe Ogun Idile kan ni, tabi enia kaa nsa si won, Ojo ti abini nma nda elomiran lamun laye, Sugbon ti aba ti mo Iru Irawo waa eleyi yio fun waa ni anfani lati mo ohun ti a waa aiye waa se. Opo elomiran ninu awon Obi loti daa igbese aiye awon omo won ru, bi apere Bi baba ba je Briclayer ti baba yi si je irawo ina, Iru eni bayi ti sise sise kori ona abayo ninu ise re, Ise Onise lo nse toripe ise awon Irawo Ile lo gbe dani ti o nse, bi iru baba yii baa bi Omo okunrin kan ti iru omo yii baa gbe Irawo ategun waa si Aiye, Baba yii le maa fi tipa tipa mun omo yii wipe dandan ise ohun ni ko se, Koye koribe, bi omo ba mun irawo Ategun waa aiye, Iru won kole se ise Iyepe ki won ni lari laye, Tabi ki Iya je Omi ki omo je Ina, ki iru iya bayi maa taa Eja tutu ki Olohun waa ti ati ibi ise Eja yii bo ni Asiri pupo, ki o waa ma fi tipa tikuku fa omo re ti o je ina wipe ise Eja ni ko se dandan Eyin Obi Eso Ara pupo, Elomiran ti da Irin ajo Omo re ru latari Ai ni imo raaraa. 

Lagbara Olohun Ti oba di ojo Kerin Osu Kesan tawa yii 4/9/2017 eo ma gbo ekun rere alaye lori Awon Irawo ti Olukuluku Eda gbe wa si aiye,


8 comments:

  1. We bless God for the wisdom of understanding towards this wonderful menber.ewenje Ben world wide kunfayakun olohun ni

    ReplyDelete
  2. Ejowo omo September 20 ni mi, ejowo iru irawo wo ni moo gbe waye sir

    ReplyDelete
  3. Ejowo omo September 20 ni mi, ejowo iru irawo wo ni moo gbe waye sir

    ReplyDelete
  4. Emi na nidi re sir, e bawa firanse ooo

    ReplyDelete